OJO NI OJO TI YEYE AROBAKE ILU IFO OLOYE OLAIDE IFALABAKE FI OMO FUN OKO ! - Insight Global News

Breaking

Saturday, August 14, 2021

OJO NI OJO TI YEYE AROBAKE ILU IFO OLOYE OLAIDE IFALABAKE FI OMO FUN OKO !

 OJO NI OJO TI IYALODE AYEDE - IFO FI SEGILOLA AJOKE IFASEUN  FUN OKO ! 

 








 














Ojo Karundinlogbon , Osu Keje, Odun ti a wa yii, ( 25 -7- 2021)  je ojo ma le gbagbe ni Ilu Ayede - Ifo ni Ipinle Ogun nigbati Iya Abiye Agbaye, Yeye Arobake ti Ilu Ifo Oloye Olaide Ifalabake fi Segilola Ajoke Ifaseun fun oko. Iwa rere ni eso eniyan gege bii opolopo  awon  alejo  ojo naa se so, nitori ero po bi Omi, eniyan to ba de ibi  igbeyawo alarinrin yii ni yi o lee royin bi Yeye Arobake se fi Ile pon oti , ti Iya Abiye  ati Alhaji Biliaminu ti gbogbo eniyan mo si  Kangiwa fi ona ro oka fun ifomofoko ogunna kan soso ti Eledumare fi da won Lola. 

 

















Iyalode Ayede- Ifo fi tayotayo oun idunnu ba asojukorohin IROHIN OWURO so oro pe " Omo rere bii Iyan ni Ajoke,  bi o tije pe Omo naa po lowo awon sibe Segilola ko yo ayo poro, O tepa mo ise owo re, pelu farabale ati suuru pataki julo Iyawo tun je omo to gboran si obi lenu ni awon naa se fi tayotayo sin losi Ile oko biotileje oju ni awon nro nitori Ajoke je  ore ati enikeji awon.' Iyawo naa ba asojukorohin IROHIN OWURO ni gbolohun ni pa didupe lowo Iya to  sowon bi eyin oju  fun imoran gbogbo Igba ti ko je ki oun o si ese  igbeyawo gbe. Lakotan Iya Abiye Agbaye gbaa ni adura pe ere  igbeyawo ti ko ni idiwon yoo je ti Segilola Ajoke Ifaseun ati oko re Oloye Tajudeen Adewale Mabadeje. Mama wa n gba awon Iya ni imoran pe ki won se ojuse to to  fun awon omo paapaa julo omobinrin ki won lee ni ifokanbale ni ojo ogbo won !

 


























Lara alejo pataki ojo naa ni Iyaafin Alabi, Iyalode Ilu Ifo ni Abe  Oba  Samuel Oladipupo Ayeronwi ti Ilu Ifo, awon  Oloye  Ilu Ifo to won soju Kabiesi,  Chief Imam Ilu Ayede pelu awon Alfa ti won so Igi igbeyawo , awon Oloye Molokun lati Ilu Ijebu- Ife, awon asoju Oba lokanojokan, awon Oloye Isese Yoruba, awon akori him naa ko gbehin pelu  Baale Ilu Ayede ati awon Oloye won. Baale Oloye Adewale Oyedele  fi nye asojukorohin IROHIN OWURO pe Iyawo je omo to ni eko ohun iteriba ti Iyalode Ayede naa si je Mama gbogbo eniyan, to ko onile ati alejo mora. Baale wa n gbaa ladura pelu ase Edumare pe ere igbeyawo yoo je ti oko ati aya.

No comments:

Post a Comment